Lefitiku 4:14
Leviticus 4:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n bá mọ̀, gbogbo ìjọ ènìyàn yóò mú akọ màlúù wá sí àgọ́ ìpàdé gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
Leviticus 4:14 in English
Leviticus 4:14 · Berean Standard Bible
when they become aware of the sin they have committed, then the assembly must bring a young bull as a sin offering and present it before the Tent of Meeting.
Context
12Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo ìyókù akọ màlúù náà ni kí ẹ gbé jáde síta lẹ́yìn ibùdó sí ibi tí a sọ di mímọ́ níbi tí à ń da eérú sí, kí ẹ sì sun wọ́n lórí iná igi, níbi eérú tí a kójọ. 13“ ‘Bí gbogbo àpapọ̀ ènìyàn Israẹli bá ṣèèṣì ṣẹ̀, tí wọ́n sì ṣe ohun tí kò yẹ kí wọ́n ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àpapọ̀ ènìyàn náà kò mọ̀ sí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n jẹ̀bi. 14Nígbà tí wọ́n bá mọ̀, gbogbo ìjọ ènìyàn yóò mú akọ màlúù wá sí àgọ́ ìpàdé gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 15Kí àwọn àgbàgbà ìjọ Israẹli gbé ọwọ́ lórí akọ ọmọ màlúù náà níwájú Olúwa. 16Kí àlùfáà tí a fi òróró yàn sì mú díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ akọ ọmọ màlúù náà wá sínú àgọ́ ìpàdé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.