Lefitiku 3:4
Leviticus 3:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀, àti gbogbo ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín.
Leviticus 3:4 in English
Leviticus 3:4 · Berean Standard Bible
both kidneys with the fat on them near the loins, and the lobe of the liver, which he is to remove with the kidneys.
Context
2Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká. 3Láti ara ọrẹ àlàáfíà ni kí ẹni náà ti mú ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa, gbogbo ọ̀nà tí ó bo nǹkan inú ẹran náà àti gbogbo ọ̀rá tí ó so mọ́ wọn. 4Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀, àti gbogbo ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín. 5Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí Olúwa. 6“ ‘Bí ó bá ṣe inú agbo ewúrẹ́ àti àgùntàn ni ó ti mú ọrẹ àlàáfíà wá fún Olúwa kí ó mú akọ tàbí abo tí kò ní àbùkù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.