Native Bible

Leviticus 3:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín.

Leviticus 3:15 in English

Leviticus 3:15 · Berean Standard Bible

both kidneys with the fat on them near the loins, and the lobe of the liver, which he is to remove with the kidneys.

Context

13Kí ó gbé ọwọ́ lé e lórí. Kí ó sì pa á ní iwájú àgọ́ ìpàdé. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká. 14Lára ọrẹ tó mú wá, kí ó mú ẹbọ sísun fún Olúwa, gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀ àti ohun gbogbo tó so mọ́ ọn. 15Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín. 16Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ, ọrẹ tí a fi iná sun, ní òórùn dídùn. Gbogbo ọ̀rá rẹ̀ jẹ́ ti Olúwa. 17“ ‘Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ìran tó ń bọ̀, ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.