Lefitiku 27:7
Leviticus 27:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọgọ́ta ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òsùwọ̀n ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún fún ọkùnrin àti òsùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin.
Leviticus 27:7 in English
Leviticus 27:7 · Berean Standard Bible
And if the person is sixty years of age or older, then your valuation shall be fifteen shekels * for the male and ten shekels for the female.
Context
5Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún sí ogún ọdún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ ogún ṣékélì fún ọkùnrin àti òsùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin. 6Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọdún márùn-ún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òsùwọ̀n ṣékélì fàdákà márùn-ún fún ọkùnrin àti òsùwọ̀n ṣékélì fàdákà mẹ́ta fún obìnrin. 7Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọgọ́ta ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òsùwọ̀n ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún fún ọkùnrin àti òsùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin. 8Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ bá tálákà púpọ̀ dé bi pé kò lè san iye owó náà, kí a mú ẹni náà wá síwájú àlùfáà, àlùfáà yóò sì dá iye owó tí ó lè san lé e gẹ́gẹ́ bí agbára ẹni náà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́. 9“ ‘Bí ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ bá jẹ́ ẹranko èyí tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún Olúwa, irú ẹran bẹ́ẹ̀ tí a bá fi fún Olúwa di mímọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.