Native Bible

Leviticus 27:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ ya gbogbo àkọ́bí ẹran sọ́tọ̀. Èyí jẹ́ ti Olúwa nípasẹ̀ òfin àkọ́bí: yálà akọ màlúù ni tàbí àgùntàn, ti Olúwa ni.

Leviticus 27:26 in English

Leviticus 27:26 · Berean Standard Bible

But no one may consecrate a firstborn of the livestock, because a firstborn belongs to the LORD. Whether it is an ox or a sheep, it is the LORD’s.

Context

24Ní ọdún ìdásílẹ̀ ilẹ̀ náà yóò padà di ti ẹni tí ó ni í, lọ́wọ́ ẹni tí a ti rà á. 25Gbogbo iye owó wọ̀nyí gbọdọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ṣékélì ibi mímọ́, ogún gera. 26“ ‘Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ ya gbogbo àkọ́bí ẹran sọ́tọ̀. Èyí jẹ́ ti Olúwa nípasẹ̀ òfin àkọ́bí: yálà akọ màlúù ni tàbí àgùntàn, ti Olúwa ni. 27Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹran tí kò mọ́, nígbà náà ni kí ó rà á padà gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀, kí ó sì fi ìdámárùn-ún lé e, tàbí bí a kò bá rà á padà kí ẹ tà á gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀. 28“ ‘Ohun tí a bá yà sí mímọ́ pátápátá láti ọwọ́ ẹnikẹ́ni sí Olúwa tàbí ẹranko tàbí ilẹ̀ tí ó jogún, òun kò gbọdọ̀ tà á kí ó rà á padà. Gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ bẹ́ẹ̀ di mímọ́ jùlọ fún Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.