Native Bible

Leviticus 27:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó bá ya ilẹ̀ náà sí mímọ́ lẹ́yìn ọdún ìdásílẹ̀ kí àlùfáà sọ iye owó tí yóò san fún ọdún tókù kí ọdún ìdásílẹ̀ mìíràn tó pé iye owó tí ó gbọdọ̀ jẹ yóò dínkù.

Leviticus 27:18 in English

Leviticus 27:18 · Berean Standard Bible

But if he consecrates his field after the Jubilee, the priest is to calculate the price in proportion to the years left until the next Year of Jubilee, so that your valuation will be reduced.

Context

16“ ‘Bí ẹnìkan bá sì ya ara ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa. Iye tí ó bá jẹ́ ni kí wọ́n ṣètò gẹ́gẹ́ bí iye èso tí a ó fi gbìn ín. Àádọ́ta ṣékélì fàdákà fún òsùwọ̀n homeri irúgbìn barle. 17Bí ó ba ṣe pé ní ọdún ìdásílẹ̀ ni ó ya ilẹ̀ náà sí mímọ́. Iye owó tí wọn sọtẹ́lẹ̀ náà ni kí o san. 18Bí ó bá ya ilẹ̀ náà sí mímọ́ lẹ́yìn ọdún ìdásílẹ̀ kí àlùfáà sọ iye owó tí yóò san fún ọdún tókù kí ọdún ìdásílẹ̀ mìíràn tó pé iye owó tí ó gbọdọ̀ jẹ yóò dínkù. 19Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà, kí ó san iye owó náà pẹ̀lú àfikún ìdámárùn-ún. Ilẹ̀ náà yóò sì di tirẹ̀. 20Bí kò bá ra ilẹ̀ náà padà tàbí bí ó bá tà á fún ẹlòmíràn kò le è ri rà padà mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.