Native Bible

Leviticus 26:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Èmi yóò fi ojúrere wò yín, Èmi yóò mú kí ẹ bí sí i, Èmi yóò jẹ́ kí ẹ pọ̀ sí i, Èmi yóò sì pa májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú yín.

Leviticus 26:9 in English

Leviticus 26:9 · Berean Standard Bible

I will turn toward you and make you fruitful and multiply you, and I will establish My covenant with you.

Context

7Ẹ̀yin yóò lé àwọn ọ̀tá yín, wọn yóò sì tipa idà kú. 8Àwọn márùn-ún péré nínú yín yóò máa ṣẹ́gun ọgọ́rùn-ún ènìyàn, àwọn ọgọ́rùn-ún yóò sì máa ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000), àwọn ọ̀tá yín yóò tipa idà kú níwájú yín. 9“ ‘Èmi yóò fi ojúrere wò yín, Èmi yóò mú kí ẹ bí sí i, Èmi yóò jẹ́ kí ẹ pọ̀ sí i, Èmi yóò sì pa májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú yín. 10Àwọn èrè oko yín yóò pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin ó máa jẹ èrè ọdún tí ó kọjá, ẹ̀yin ó sì kó wọn jáde, kí ẹ̀yin lè rí ààyè kó tuntun sí. 11Èmi yóò kọ́ àgọ́ mímọ́ mi sí àárín yín. Èmi kò sì ní kórìíra yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.