Lefitiku 26:45
Leviticus 26:45 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí wọn, èmi ó rántí májẹ̀mú mi tí mo ti ṣe pẹ̀lú baba ńlá wọn. Àwọn tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láti jẹ́ Ọlọ́run wọn. Èmi ni Olúwa.’ ”
Leviticus 26:45 in English
Leviticus 26:45 · Berean Standard Bible
But for their sake I will remember the covenant with their fathers, whom I brought out of the land of Egypt in the sight of the nations, that I might be their God. I am the LORD.”
Context
43Àwọn ènìyàn náà yóò sì fi ilẹ̀ náà sílẹ̀, yóò sì ní ìsinmi rẹ̀ nígbà tí ó bá wà lófo láìsí wọn níbẹ̀. Wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé wọ́n kọ àwọn òfin mi. Wọ́n sì kórìíra àwọn àṣẹ mi. 44Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nígbà tí wọ́n bá wà nílé àwọn ọ̀tá wọn, èmi kì yóò ta wọ́n nù, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò kórìíra wọn pátápátá, èyí tí ó lè mú mi dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn. 45Nítorí wọn, èmi ó rántí májẹ̀mú mi tí mo ti ṣe pẹ̀lú baba ńlá wọn. Àwọn tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láti jẹ́ Ọlọ́run wọn. Èmi ni Olúwa.’ ” 46Ìwọ̀nyí ni òfin àti ìlànà tí Olúwa fún Mose ní orí òkè Sinai láàrín òun àti àwọn ọmọ Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.