Native Bible

Leviticus 26:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ní ìbínú mi, èmi yóò korò sí yín, èmi tìkára mi yóò fìyà jẹ yín ní ìgbà méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.

Leviticus 26:28 in English

Leviticus 26:28 · Berean Standard Bible

then I will walk in fury against you, and I, even I, will punish you sevenfold for your sins.

Context

26Èmi yóò dá ìpèsè oúnjẹ yín dúró, dé bi pé: inú ààrò kan ni obìnrin mẹ́wàá yóò ti máa se oúnjẹ yín. Òsùwọ̀n ni wọn yóò fi máa yọ oúnjẹ yín, ẹ ó jẹ ṣùgbọ́n, ẹ kò ní yó. 27“ ‘Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ kò bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì lòdì sí mi, 28ní ìbínú mi, èmi yóò korò sí yín, èmi tìkára mi yóò fìyà jẹ yín ní ìgbà méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. 29Ebi náà yóò pa yín dé bi pé ẹ ó máa jẹ ẹran-ara àwọn ọmọ yín ọkùnrin, àti àwọn ọmọ yín obìnrin. 30Èmi yóò wó àwọn pẹpẹ òrìṣà yín, lórí òkè níbi tí ẹ ti ń sìn, Èmi yóò sì kó òkú yín jọ, sórí àwọn òkú òrìṣà yín. Èmi ó sì kórìíra yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.