Native Bible

Leviticus 26:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò mú idà wá bá yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín láti fi gbẹ̀san májẹ̀mú mi tí ẹ kò pamọ́. Bí ẹ ba sálọ sí ìlú yín fún ààbò, Èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín yín, àwọn ọ̀tá yín, yóò sì ṣẹ́gun yín.

Leviticus 26:25 in English

Leviticus 26:25 · Berean Standard Bible

And I will bring a sword against you to execute the vengeance of the covenant. Though you withdraw into your cities, I will send a plague among you, and you will be delivered into the hand of the enemy.

Context

23“ ‘Bí ẹ kò bá tún yípadà lẹ́yìn gbogbo ìjìyà wọ̀nyí, tí ẹ sì tẹ̀síwájú láti lòdì sí mi. 24Èmi náà yóò lòdì sí yín. Èmi yóò tún fa ìjìyà yín le ní ìlọ́po méje ju ti ìṣáájú. 25Èmi yóò mú idà wá bá yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín láti fi gbẹ̀san májẹ̀mú mi tí ẹ kò pamọ́. Bí ẹ ba sálọ sí ìlú yín fún ààbò, Èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín yín, àwọn ọ̀tá yín, yóò sì ṣẹ́gun yín. 26Èmi yóò dá ìpèsè oúnjẹ yín dúró, dé bi pé: inú ààrò kan ni obìnrin mẹ́wàá yóò ti máa se oúnjẹ yín. Òsùwọ̀n ni wọn yóò fi máa yọ oúnjẹ yín, ẹ ó jẹ ṣùgbọ́n, ẹ kò ní yó. 27“ ‘Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ kò bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì lòdì sí mi,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.