Lefitiku 22:6
Leviticus 22:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni náà tí ó fọwọ́ kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú ọrẹ mímọ́ àyàfi bí ó bá wẹ ara rẹ̀.
Leviticus 22:6 in English
Leviticus 22:6 · Berean Standard Bible
the man who touches any of these will remain unclean until evening. He must not eat from the sacred offerings unless he has bathed himself with water.
Context
4“ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Aaroni bá ní ààrùn ara tí ń ran ni, tàbí ìtújáde nínú ara. Ó lè má jẹ ọrẹ mímọ́ náà títí di ìgbà tí a ó fi wẹ̀ ẹ́ mọ́. Òun tún lè di aláìmọ́ bí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí òkú nǹkan bá sọ di àìmọ́ tàbí bí ó bá farakan ẹnikẹ́ni tí ó ní ìtújáde. 5Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan èyíkéyìí nínú ohun tí ń rákò, tí ó sọ ọ́ di aláìmọ́, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó sọ ọ́ di àìmọ́, ohunkóhun yówù kí àìmọ́ náà jẹ́. 6Ẹni náà tí ó fọwọ́ kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú ọrẹ mímọ́ àyàfi bí ó bá wẹ ara rẹ̀. 7Bí oòrùn bá wọ̀, ẹni náà di mímọ́, lẹ́yìn náà ni ó tó le jẹ ọrẹ mímọ́, torí pé wọ́n jẹ́ oúnjẹ rẹ̀. 8Kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti kú sílẹ̀, tàbí tí ẹranko fàya, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di aláìmọ́. Èmi ni Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.