Lefitiku 22:25
Leviticus 22:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ kò gbọdọ̀ gba irú ẹranko bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò kankan láti fi rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ sí Ọlọ́run yín. A kò nígbà wọ́n fún yín nítorí pé wọ́n ní àbùkù, wọ́n sì díbàjẹ́.’ ”
Leviticus 22:25 in English
Leviticus 22:25 · Berean Standard Bible
Neither you nor a foreigner shall present food to your God from any such animal. They will not be accepted on your behalf, because they are deformed and flawed.’”
Context
23Ẹ le mú màlúù tàbí àgùntàn tí ó ní àbùkù tàbí tí ó yọ iké wá fún ọrẹ àtinúwá, ṣùgbọ́n kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ ẹ̀jẹ́. 24Ẹ má ṣe fi ẹranko tí kóró ẹpọ̀n rẹ̀ fọ́ tàbí tí a tẹ̀, tàbí tí a yà tàbí tí a là rú ẹbọ sí Olúwa. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí ní ilẹ̀ yín. 25Ẹ kò gbọdọ̀ gba irú ẹranko bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò kankan láti fi rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ sí Ọlọ́run yín. A kò nígbà wọ́n fún yín nítorí pé wọ́n ní àbùkù, wọ́n sì díbàjẹ́.’ ” 26Olúwa sọ fún Mose pé, 27“Nígbà tí màlúù bá bímọ, tí àgùntàn bímọ, tí ewúrẹ́ sì bímọ, ọmọ náà gbọdọ̀ wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀ fún ọjọ́ méje. Láti ọjọ́ kẹjọ ni ó ti di ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ àfinásun sí Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.