Native Bible

Leviticus 22:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ọmọbìnrin àlùfáà bá fẹ́ ẹni tí kì í ṣe àlùfáà, kò gbọdọ̀ jẹ nínú èyíkéyìí nínú ohun ọrẹ mímọ́.

Leviticus 22:12 in English

Leviticus 22:12 · Berean Standard Bible

If the priest’s daughter is married to a man other than a priest, she is not to eat of the sacred contributions.

Context

10“ ‘Kò sí ẹnikẹ́ni lẹ́yìn ìdílé àlùfáà tí ó le jẹ ọrẹ mímọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni, àlejò àlùfáà tàbí alágbàṣe rẹ̀ kò le jẹ ẹ́. 11Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá ra ẹrú, pẹ̀lú owó, tàbí tí a bí ẹrú kan nínú ìdílé rẹ̀, ẹrú náà lè jẹ oúnjẹ rẹ̀. 12Bí ọmọbìnrin àlùfáà bá fẹ́ ẹni tí kì í ṣe àlùfáà, kò gbọdọ̀ jẹ nínú èyíkéyìí nínú ohun ọrẹ mímọ́. 13Ṣùgbọ́n bí ọmọbìnrin àlùfáà bá jẹ́ opó tàbí tí a ti kọ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò lọ́mọ tí ó sì padà sínú ilé baba rẹ̀ láti máa gbé bẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀, ó le jẹ oúnjẹ baba rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àlejò tí kò lẹ́tọ̀ọ́ kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú oúnjẹ náà. 14“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì jẹ ọrẹ mímọ́ kan, ó gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe lórí ẹbọ náà fún àlùfáà, kí ó sì fi ìdámárùn-ún ohun tí ọrẹ náà jẹ́ kún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.