Native Bible

Leviticus 21:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kò gbọdọ̀ sí ẹnikẹ́ni yálà ó rọ lápá lẹ́sẹ̀,

Leviticus 21:19 in English

Leviticus 21:19 · Berean Standard Bible

no man who has a broken foot or hand,

Context

17“Sọ fún Aaroni pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú irú-ọmọ rẹ̀ ní ìran-ìran wọn, tí ó bá ní ààrùn kan, kí ó má ṣe súnmọ́ tòsí láti rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọ́run rẹ̀. 18Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àbùkù kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi ẹbọ náà. Kò gbọdọ̀ sí afọ́jú tàbí arọ, alábùkù ara tàbí àwọn tí ara wọn kò pé. 19Kò gbọdọ̀ sí ẹnikẹ́ni yálà ó rọ lápá lẹ́sẹ̀, 20tàbí tí ó jẹ́ abuké, tàbí tí ó ya aràrá tàbí tí ó ní àìsàn ojú tàbí tí ó ní egbò tàbí tí a ti yọ nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀. 21Ẹnikẹ́ni tí ó ní àbùkù nínú irú-ọmọ Aaroni àlùfáà kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí láti rú ẹbọ tí fi iná sun sí Olúwa. Nítorí pé ó jẹ́ alábùkù, kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí láti rú ẹbọ àkàrà sí Ọlọ́run rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.