Native Bible

Leviticus 20:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Torí náà ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, torí pé, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

Leviticus 20:7 in English

Leviticus 20:7 · Berean Standard Bible

Consecrate yourselves, therefore, and be holy, because I am the LORD your God.

Context

5Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ àti gbogbo ìdílé rẹ̀, èmi yóò sì ké wọn kúrò láàrín àwọn ènìyàn wọn, òun àti gbogbo àwọn tí ó jọ ṣe àgbèrè tọ òrìṣà Moleki lẹ́yìn. 6“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá tọ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ àti àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn lọ, tí ó sì ṣe àgbèrè tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, Èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 7“ ‘Torí náà ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, torí pé, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín. 8Ẹ máa kíyèsi àṣẹ mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́. Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́. 9“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé baba tàbí ìyá rẹ̀ ni kí ẹ pa, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí ara rẹ̀ torí pé ó ti ṣépè lé baba àti ìyá rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.