Native Bible

Leviticus 20:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún mi torí pé, Èmi Olúwa fẹ́ mímọ́. Mó sì ti yà yín kúrò nínú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kí ẹ le jẹ́ tèmi.

Leviticus 20:26 in English

Leviticus 20:26 · Berean Standard Bible

You are to be holy to Me because I, the LORD, am holy, and I have set you apart from the nations to be My own.

Context

24Ṣùgbọ́n mo ti sọ fún yín pé, “Ẹ̀yin ni yóò jogún ilẹ̀ wọn, Èmi yóò sì fi fún yín láti jogún ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.” Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn yòókù. 25“ ‘Ẹ gbọdọ̀ pààlà sáàrín ẹran tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Láàrín ẹyẹ tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ àwọn ẹranko tàbí ẹyẹ tàbí ohunkóhun tí ń rìn lórí ilẹ̀: èyí tí mo yà sọ́tọ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí ohun àìmọ́. 26Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún mi torí pé, Èmi Olúwa fẹ́ mímọ́. Mó sì ti yà yín kúrò nínú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kí ẹ le jẹ́ tèmi. 27“ ‘Ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí oṣó láàrín yín ni kí ẹ pa. Ẹ sọ wọ́n ní òkúta, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.