Lefitiku 20:17
Leviticus 20:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ arábìnrin rẹ̀ yálà ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀, ohun ìtìjú ni èyí, ẹ ó gé wọn kúrò lójú àwọn ènìyàn wọn, ó ti tàbùkù arábìnrin rẹ̀. Ẹ̀bi rẹ̀ yóò wá sórí rẹ̀.
Leviticus 20:17 in English
Leviticus 20:17 · Berean Standard Bible
If a man marries his sister, whether the daughter of his father or of his mother, and they have sexual relations,* it is a disgrace. They must be cut off in the sight of their people. He has uncovered the nakedness of his sister; he shall bear his iniquity.
Context
15“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ẹranko lòpọ̀, ẹ gbọdọ̀ pa ọkùnrin náà àti ẹranko náà. 16“ ‘Bí obìnrin kan bá súnmọ́ ẹranko tí ó sì bá a lòpọ̀ obìnrin náà àti ẹranko náà ni kí ẹ pa, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì wà lórí ara wọn. 17“ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ arábìnrin rẹ̀ yálà ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀, ohun ìtìjú ni èyí, ẹ ó gé wọn kúrò lójú àwọn ènìyàn wọn, ó ti tàbùkù arábìnrin rẹ̀. Ẹ̀bi rẹ̀ yóò wá sórí rẹ̀. 18“ ‘Bí ọkùnrin kan bá súnmọ́ obìnrin, ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀. Ó ti tú orísun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Òun náà sì gbà á láààyè. Àwọn méjèèjì ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn wọn. 19“ ‘Má ṣe bá arábìnrin baba tàbí ti ìyá rẹ lòpọ̀, nítorí o ti tú ìhòhò ìbátan rẹ, ẹ̀yin méjèèjì ni yóò ru ẹ̀bi yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.