Lefitiku 19:6
Leviticus 19:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú u náà ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ tàbí ní ọjọ́ kejì; èyí tí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta ni kí ẹ fi iná sun.
Leviticus 19:6 in English
Leviticus 19:6 · Berean Standard Bible
It shall be eaten on the day you sacrifice it, or on the next day; but what remains on the third day must be burned up.
Context
4“ ‘Ẹ má ṣe yípadà tọ ère òrìṣà lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ rọ ère òrìṣà idẹ fún ara yín. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín. 5“ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa, kí ẹ̀yin kí ó ṣe é ní ọ̀nà tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò yín. 6Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú u náà ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ tàbí ní ọjọ́ kejì; èyí tí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta ni kí ẹ fi iná sun. 7Bí ẹ bá jẹ nínú èyí tí ó ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, àìmọ́ ni èyí jẹ́, kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. 8Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù, nítorí pé ó ti ba ohun mímọ́ Olúwa jẹ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.