Lefitiku 19:10
Leviticus 19:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátápátá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú ọgbà àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
Leviticus 19:10 in English
Leviticus 19:10 · Berean Standard Bible
You must not strip your vineyard bare or gather its fallen grapes. Leave them for the poor and the foreigner. I am the LORD your God.
Context
8Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù, nítorí pé ó ti ba ohun mímọ́ Olúwa jẹ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 9“ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá kórè nǹkan oko yín, kí ẹ̀yin kí ó fi díẹ̀ sílẹ̀ láìkórè ní àwọn igun oko yín, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣa ẹ̀ṣẹ́ (nǹkan oko tí ẹ ti gbàgbé tàbí tí ó bọ́ sílẹ̀). 10Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátápátá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú ọgbà àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín. 11“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ parọ́.
“ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ tan ara yín jẹ. 12“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.