Native Bible

Leviticus 17:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

tí kò sì mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

Leviticus 17:9 in English

Leviticus 17:9 · Berean Standard Bible

but does not bring it to the entrance to the Tent of Meeting to sacrifice it to the LORD, that man must be cut off from his people.

Context

7Nítorí náà, kí wọn má ṣe rú ẹbọ wọn sí ère ẹranko mọ́, nínú èyí tí wọ́n ti ṣe àgbèrè tọ̀ lọ. Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé láti ìran dé ìran wọn tí ń bọ̀.’ 8“Kí ó sọ fún wọn pé, ‘Ọkùnrin yówù kí ó jẹ́ ní ìdílé Israẹli tàbí ti àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn tí ó bá rú ẹbọ sísun tàbí ṣe ẹbọ 9tí kò sì mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 10“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀ yálà nínú ìdílé Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn, Èmi yóò bínú sí irú ẹni náà tí ó jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 11Nítorí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá wà, èmi sì ti fi fún yín lórí pẹpẹ fún ètùtù ọkàn yín: nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni a fi ń ṣe ètùtù fún ẹ̀mí ènìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.