Lefitiku 16:29
Leviticus 16:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín, pé ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ni ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan, yálà onílé tàbí àlejò tí ó ń gbé pẹ̀lú yín.
Leviticus 16:29 in English
Leviticus 16:29 · Berean Standard Bible
This is to be a permanent statute for you: On the tenth day of the seventh month, you shall humble yourselves * and not do any work—whether the native or the foreigner who resides among you—
Context
27Ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti mú ẹ̀jẹ̀ wọn wá sí Ibi Mímọ́ Jùlọ ni kí a gbe jáde kúrò ní ibùdó. Awọ wọn ni a ó fi iná sun bákan náà. 28Ẹni tí ó sun wọ́n yóò sì fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì wẹ ara rẹ̀, lẹ́yìn èyí ni ó tó le wọ ibùdó. 29“Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín, pé ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ni ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan, yálà onílé tàbí àlejò tí ó ń gbé pẹ̀lú yín. 30Torí pé ní ọjọ́ yìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún yín láti sọ yín di mímọ́, kí ẹ̀yin bá à le mọ́ níwájú Olúwa yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo. 31Ọjọ́ yìí yóò jẹ́ ọjọ́ ìsinmi pátápátá fún un yín, ẹ̀yin yóò sì ṣẹ́ ara yín. Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.