Lefitiku 16:19
Leviticus 16:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà, òun yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sórí rẹ̀ pẹ̀lú ìka rẹ̀ nígbà méje láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ àti láti sọ ọ́ dí mímọ́ kúrò nínú àìmọ́ àwọn ọmọ Israẹli.
Leviticus 16:19 in English
Leviticus 16:19 · Berean Standard Bible
He is to sprinkle some of the blood on it with his finger seven times to cleanse it and consecrate it from the uncleanness of the Israelites.
Context
17Kí ó má ṣe sí ẹyọ ènìyàn kan nínú àgọ́ ìpàdé nígbà tí òun bá wọ Ibi Mímọ́ Jùlọ lọ láti ṣe ètùtù, títí di ìgbà tí yóò fi jáde lẹ́yìn tí ó ba ṣe ètùtù fúnra rẹ̀ fún ìdílé rẹ̀ àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ Israẹli. 18“Lẹ́yìn náà òun yóò lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú Olúwa, yóò sì ṣe ètùtù fún pẹpẹ náà. Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti nínú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà, yóò sì fi sí orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwo pẹpẹ náà yíká. 19Lẹ́yìn náà, òun yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sórí rẹ̀ pẹ̀lú ìka rẹ̀ nígbà méje láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ àti láti sọ ọ́ dí mímọ́ kúrò nínú àìmọ́ àwọn ọmọ Israẹli. 20“Lẹ́yìn ti Aaroni ti parí ṣíṣe ètùtù ti Ibi Mímọ́ Jùlọ, ti àgọ́ ìpàdé àti ti pẹpẹ, òun yóò sì mú ààyè ewúrẹ́ wá. 21Aaroni yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, yóò sì jẹ́wọ́ gbogbo ìwà búburú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ara Israẹli lé e lórí. Gbogbo ìrékọjá wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni yóò sì gbé ka orí ewúrẹ́ náà. Yóò sì rán an lọ sí ijù láti ọwọ́ ẹni tí a yàn fún iṣẹ́ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.