Native Bible

Leviticus 16:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Aaroni yóò sì mú akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. Yóò sì pa akọ màlúù náà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀.

Leviticus 16:11 in English

Leviticus 16:11 · Berean Standard Bible

When Aaron presents the bull for his sin offering and makes atonement for himself and his household, he is to slaughter the bull for his own sin offering.

Context

9Aaroni yóò sì mú ewúrẹ́ tí ìbò Olúwa mú, yóò sì fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 10Ṣùgbọ́n ewúrẹ́ tí ìbò bá mú gẹ́gẹ́ bí ewúrẹ́ ìpààrọ̀ ni a ó mú wá láààyè síwájú Olúwa láti fi ṣe ètùtù sí i àti láti jẹ́ kí ó lọ lọ́fẹ̀ẹ́, sí aginjù. 11“Aaroni yóò sì mú akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. Yóò sì pa akọ màlúù náà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀. 12Yóò sì mú àwo tùràrí tí ó kún fún èédú tí a ti sun pẹ̀lú iná láti orí pẹpẹ wá síwájú Olúwa: àti ẹ̀kúnwọ́ méjì tùràrí tí a gún kúnná yóò sì mú un wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa. 13Yóò sì fi tùràrí náà lé orí iná níwájú Olúwa: kí èéfín tùràrí náà ba à le bo ìtẹ́ àánú tí ó wà ní orí àpótí ẹ̀rí kí o má ba à kú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.