Native Bible

Leviticus 15:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Bí nǹkan ọkùnrin kan bá tú jáde, kí ó wẹ gbogbo ara rẹ̀, kí ó wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

Leviticus 15:16 in English

Leviticus 15:16 · Berean Standard Bible

When a man has an emission of semen, he must bathe his whole body with water, and he will be unclean until evening.

Context

14Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, kí ó sì wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa, kí ó sì kó wọn fún àlùfáà. 15Kí àlùfáà fi wọ́n rú ẹbọ: ọ̀kan fún ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ọrẹ ẹbọ sísun níwájú Olúwa ní ipò ọkùnrin náà nítorí ìsunjáde rẹ̀. 16“ ‘Bí nǹkan ọkùnrin kan bá tú jáde, kí ó wẹ gbogbo ara rẹ̀, kí ó wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 17Yálà àwọ̀ tàbí aṣọ tí nǹkan ọkùnrin bá dà sí lórí ni kí ẹ fọ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ di ìrọ̀lẹ́. 18Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin lòpọ̀ tí nǹkan ọkùnrin sì tú jáde lára rẹ̀. Àwọn méjèèjì gbọdọ̀ fi omi wẹ̀, kí wọ́n sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.