Native Bible

Leviticus 14:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, lẹ́yìn èyí ó ti di mímọ́. Lẹ́yìn náà ó le wá sínú ibùdó ṣùgbọ́n kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ méje.

Leviticus 14:8 in English

Leviticus 14:8 · Berean Standard Bible

The one being cleansed must wash his clothes, shave off all his hair, and bathe with water; then he will be ceremonially clean. Afterward, he may enter the camp, but he must remain outside his tent for seven days.

Context

6Lẹ́yìn náà kí ó ri ààyè ẹyẹ pẹ̀lú igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí a ti pa sínú omi náà. 7Ìgbà méje ni kí o wọ́n omi yìí sí ara ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ kúrò nínú ààrùn ara náà kí ó ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ ní ìta gbangba. 8“Ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, lẹ́yìn èyí ó ti di mímọ́. Lẹ́yìn náà ó le wá sínú ibùdó ṣùgbọ́n kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ méje. 9Kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ ní ọjọ́ keje: irun orí rẹ̀, irùngbọ̀n rẹ̀, irun ìpéǹpéjú rẹ̀, àti gbogbo irun rẹ̀ tókù. Kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì mọ́. 10“Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àgbò aláìlábùkù méjì àti abo ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí wọn kò ní àlébù wá, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí à pòpọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ àti òsùwọ̀n lógù òróró kan.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.