Lefitiku 14:43
Leviticus 14:43 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Bí ààrùn yìí bá tún farahàn lẹ́yìn tí a ti yọ àwọn òkúta wọ̀nyí tí a sì ti ha ilé náà ti a sì tún rẹ́ ẹ.
Leviticus 14:43 in English
Leviticus 14:43 · Berean Standard Bible
If the mildew reappears in the house after the stones have been torn out and the house has been scraped and replastered,
Context
41Yóò sì mú kí wọ́n ha ògiri inú ilé náà yíká. Gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé náà tí ó ti ha ni kí wọ́n kó dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú náà. 42Òkúta mìíràn ni kí wọ́n fi dípò àwọn tí a ti yọ dànù, kí wọ́n sì rẹ́ ilé náà pẹ̀lú àwọn ohun ìrẹ́lé tuntun. 43“Bí ààrùn yìí bá tún farahàn lẹ́yìn tí a ti yọ àwọn òkúta wọ̀nyí tí a sì ti ha ilé náà ti a sì tún rẹ́ ẹ. 44Àlùfáà yóò tún lọ yẹ̀ ẹ́ wò bí ààrùn náà bá tún gbilẹ̀ sí i nínú ilé náà: ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí, ilé náà jẹ́ aláìmọ́. 45Wíwó ni kí a wó o, gbogbo òkúta ilé náà, àwọn igi àti gbogbo ohun tí a fi rẹ́ ẹ ni kí a kó jáde nínú ìlú sí ibi tí a kà sí àìmọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.