Lefitiku 14:4
Leviticus 14:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí a mú ààyè ẹyẹ mímọ́ méjì, igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù wá fún ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́.
Leviticus 14:4 in English
Leviticus 14:4 · Berean Standard Bible
the priest shall order that two live clean birds, cedar wood, scarlet yarn, and hyssop be brought for the one to be cleansed.
Context
2“Èyí ni àwọn ìlànà fún ẹni tí ààrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ní àkókò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, bí a bá mú un tọ àlùfáà wá. 3Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò ní ẹ̀yìn ibùdó bí ara rẹ̀ bá ti yá kúrò nínú ààrùn ẹ̀tẹ̀ náà. 4Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí a mú ààyè ẹyẹ mímọ́ méjì, igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù wá fún ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́. 5Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí wọn pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ tó wà nínú ìkòkò amọ̀. 6Lẹ́yìn náà kí ó ri ààyè ẹyẹ pẹ̀lú igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí a ti pa sínú omi náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.