Native Bible

Leviticus 14:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn náà kí ó fi àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé rú ẹbọ níwọ̀n tí agbára rẹ̀ mọ.

Leviticus 14:30 in English

Leviticus 14:30 · Berean Standard Bible

Then he must sacrifice the turtledoves or young pigeons, whichever he can afford,

Context

28Àlùfáà yóò sì mú lára òróró ọwọ́ rẹ̀ sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ní ibi kan náà tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi sí. 29Kí àlùfáà fi ìyókù nínú òróró ọwọ́ rẹ̀ sí orí ẹni náà tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún, láti ṣe ètùtù fún un ní iwájú Olúwa. 30Lẹ́yìn náà kí ó fi àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé rú ẹbọ níwọ̀n tí agbára rẹ̀ mọ. 31Ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù níwájú Olúwa ní ipò ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́.” 32Òfin nìyí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ààrùn ara tí ó le ran tí kò sì lágbára láti rú ẹbọ tí ó yẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ bí a ti fi lélẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.