Lefitiku 14:23
Leviticus 14:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Kí ó mú wọn wá ní ọjọ́ kẹjọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ síwájú àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa.
Leviticus 14:23 in English
Leviticus 14:23 · Berean Standard Bible
On the eighth day he is to bring them for his cleansing to the priest at the entrance to the Tent of Meeting before the LORD.
Context
21“Bí ẹni náà bá jẹ́ tálákà tí kò sì le è kó gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, kí ó mú ọ̀dọ́ àgbò kan bí ẹbọ ẹ̀bi, tí yóò fì, láti ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára, a pò mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ òsùwọ̀n lógù òróró 22àti àdàbà méjì tàbí ẹyẹlé méjì èyí tí agbára rẹ̀ ká, ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun. 23“Kí ó mú wọn wá ní ọjọ́ kẹjọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ síwájú àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa. 24Àlùfáà náà yóò sì mú ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú lógù òróró yóò sì fì wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì. 25Kí ó pa ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi kí ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kí ó fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.