Lefitiku 13:7
Leviticus 13:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n bí èélá náà bá ń ràn ká awọ ara rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti fi ara rẹ̀ han àlùfáà láti sọ pé ó ti mọ́. Ó tún gbọdọ̀ fi ara rẹ̀ hàn níwájú àlùfáà.
Leviticus 13:7 in English
Leviticus 13:7 · Berean Standard Bible
But if the rash spreads further on his skin after he has shown himself to the priest for his cleansing, he must present himself again to the priest.
Context
5Ní ọjọ́ keje ni kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ó bá rí i pé egbò náà wà síbẹ̀ tí kò sì ràn ká àwọ̀ ara, kí ó tún fi pamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn. 6Ní ọjọ́ keje ni kí àlùfáà tún padà yẹ̀ ẹ́ wò, bí egbò náà bá ti san tí kò sì ràn ká awọ ara rẹ̀. Kí àlùfáà pè é ní mímọ́. Kí ọkùnrin náà fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì mọ́. 7Ṣùgbọ́n bí èélá náà bá ń ràn ká awọ ara rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó ti fi ara rẹ̀ han àlùfáà láti sọ pé ó ti mọ́. Ó tún gbọdọ̀ fi ara rẹ̀ hàn níwájú àlùfáà. 8Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí èélá náà bá ràn ká awọ ara rẹ̀, kí àlùfáà fihàn pé kò mọ́. Ààrùn ara tí ń ràn ni èyí. 9“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ààrùn awọ ara tí ń ràn yìí ni kí a mú wá sọ́dọ̀ àlùfáà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.