Lefitiku 13:58
Leviticus 13:58 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Aṣọ náà, aṣọ títa náà, aṣọ híhun náà tàbí ohun èlò awọ náà tí a ti fọ̀ tí ó sì mọ́ lọ́wọ́ ẹ̀tẹ̀ náà ni kí a tún fọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Yóò sì di mímọ́.”
Leviticus 13:58 in English
Leviticus 13:58 · Berean Standard Bible
If the mildew disappears from the fabric, weave, or knit, or any leather article after washing, then it is to be washed again, and it will be clean.
Context
56Bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò ti ẹ̀tẹ̀ náà bá ti kúrò níbẹ̀, lẹ́yìn tí a ti fọ ohunkóhun tí ó mú, kí ó ya ibi tí ó bàjẹ́ kúrò lára aṣọ náà, awọ náà, aṣọ híhun náà tàbí aṣọ títa náà. 57Ṣùgbọ́n bí ó bá tún ń farahàn níbi aṣọ náà, lára aṣọ títa náà, lára aṣọ híhun náà tàbí lára ohun èlò awọ náà, èyí fihàn pé ó ń ràn ká. Gbogbo ohun tí ẹ̀tẹ̀ náà bá wà lára rẹ̀ ni kí ẹ fi iná sun. 58Aṣọ náà, aṣọ títa náà, aṣọ híhun náà tàbí ohun èlò awọ náà tí a ti fọ̀ tí ó sì mọ́ lọ́wọ́ ẹ̀tẹ̀ náà ni kí a tún fọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Yóò sì di mímọ́.” 59Èyí ni òfin ààrùn, nínú aṣọ bubusu, ti aṣọ ọ̀gbọ̀, ti aṣọ títa, ti aṣọ híhun tàbí ti ohun èlò awọ, láti fihàn bóyá wọ́n wà ní mímọ́ tàbí àìmọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.