Lefitiku 13:37
Leviticus 13:37 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdájọ́ àlùfáà pé ẹni náà kò mọ́, tí ojú làpálàpá náà kò bá yípadà, tí irun dúdú si ti hù jáde lójú rẹ̀. Làpálàpá náà ti san. Òun sì ti di mímọ́. Kí àlùfáà fi í hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti di mímọ́.
Leviticus 13:37 in English
Leviticus 13:37 · Berean Standard Bible
If, however, in his sight the scaly outbreak is unchanged and black hair has grown in it, then it has healed. He is clean, and the priest is to pronounce him clean.
Context
35Ṣùgbọ́n bí làpálàpá náà bá ràn ká àwọ̀ ara rẹ̀ lẹ́yìn tí a ti fihàn pé ó ti mọ́. 36Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí làpálàpá náà bá ràn ká àwọ̀ ara; kí àlùfáà má ṣe yẹ irun pupa fẹ́ẹ́rẹ́ wò mọ́. Ẹni náà ti di aláìmọ́. 37Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdájọ́ àlùfáà pé ẹni náà kò mọ́, tí ojú làpálàpá náà kò bá yípadà, tí irun dúdú si ti hù jáde lójú rẹ̀. Làpálàpá náà ti san. Òun sì ti di mímọ́. Kí àlùfáà fi í hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti di mímọ́. 38“Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá ní ojú àpá funfun lára àwọ̀ ara rẹ̀. 39Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ojú àpá náà bá funfun ààrùn ara tí kò léwu ni èyí tí ó farahàn lára rẹ̀, ẹni náà mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.