Native Bible

Leviticus 11:43 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi ohun kan tí ń rákò, sọ ara yín di ìríra, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi wọ́n sọ ara yín di aláìmọ́, tí ẹ̀yin yóò fi ti ipa wọn di eléèérí.

Leviticus 11:43 in English

Leviticus 11:43 · Berean Standard Bible

Do not defile yourselves by any crawling creature; do not become unclean or defiled by them.

Context

41“ ‘Ìríra ni gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ jẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n. 42Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ń rìn ká orí ilẹ̀ yálà ó ń fàyàfà tàbí ó ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, tàbí ó ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ̀ rìn ìríra ni èyí. 43Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi ohun kan tí ń rákò, sọ ara yín di ìríra, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi wọ́n sọ ara yín di aláìmọ́, tí ẹ̀yin yóò fi ti ipa wọn di eléèérí. 44Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ torí pé mo jẹ́ mímọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ ohunkóhun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀. 45Èmi ni Olúwa tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín torí náà, ẹ jẹ́ mímọ́ torí pé mímọ́ ni èmi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.