Native Bible

Leviticus 11:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ọ̀kan nínú wọn bá kú tí wọ́n sì bọ́ sórí nǹkan kan, bí ó ti wù kí irú ohun náà wúlò tó, yóò di aláìmọ́ yálà aṣọ ni a fi ṣe é ni tàbí igi, irun aṣọ tàbí àpò, ẹ sọ ọ́ sínú omi yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ lẹ́yìn náà ni yóò tó di mímọ́.

Leviticus 11:32 in English

Leviticus 11:32 · Berean Standard Bible

When one of them dies and falls on something, that article becomes unclean; any article of wood, clothing, leather, sackcloth, or any implement used for work must be rinsed with water and will remain unclean until evening; then it will be clean.

Context

30Ọmọnílé, alágẹmọ, aláǹgbá, ìgbín àti ọ̀gà. 31Nínú gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ìwọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 32Bí ọ̀kan nínú wọn bá kú tí wọ́n sì bọ́ sórí nǹkan kan, bí ó ti wù kí irú ohun náà wúlò tó, yóò di aláìmọ́ yálà aṣọ ni a fi ṣe é ni tàbí igi, irun aṣọ tàbí àpò, ẹ sọ ọ́ sínú omi yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ lẹ́yìn náà ni yóò tó di mímọ́. 33Bí èyíkéyìí nínú wọn bá bọ́ sínú ìkòkò amọ̀, gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀ ti di àìmọ́. Ẹ gbọdọ̀ fọ ìkòkò náà. 34Bí omi inú ìkòkò náà bá dà sórí èyíkéyìí nínú oúnjẹ tí ẹ̀ ń jẹ oúnjẹ náà di aláìmọ́. Gbogbo ohun mímu tí a lè mú jáde láti inú rẹ̀ di àìmọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.