Lefitiku 11:29
Leviticus 11:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń rìn lórí ilẹ̀ ìwọ̀nyí ni ó jẹ́ àìmọ́ fún yín: Asé, eku àti oríṣìíríṣìí aláǹgbá,
Leviticus 11:29 in English
Leviticus 11:29 · Berean Standard Bible
The following creatures that move along the ground are unclean for you: the mole, the mouse, any kind of great lizard,
Context
27Nínú gbogbo ẹranko tí ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, àwọn tí ń fi èékánná wọn rìn jẹ́ aláìmọ́ fún yín, ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 28Ẹni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Wọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín. 29“ ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń rìn lórí ilẹ̀ ìwọ̀nyí ni ó jẹ́ àìmọ́ fún yín: Asé, eku àti oríṣìíríṣìí aláǹgbá, 30Ọmọnílé, alágẹmọ, aláǹgbá, ìgbín àti ọ̀gà. 31Nínú gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ìwọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.