Lefitiku 11:24
Leviticus 11:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Nípa àwọn wọ̀nyí ni ẹ le fi sọ ara yín di àìmọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
Leviticus 11:24 in English
Leviticus 11:24 · Berean Standard Bible
These creatures will make you unclean. Whoever touches their carcasses will be unclean until evening,
Context
22Nínú àwọn wọ̀nyí ni ẹ lè jẹ onírúurú eṣú, onírúurú ìrẹ̀ àti onírúurú tata. 23Ṣùgbọ́n gbogbo ohun ìyókù tí ń fò, tí ń rákò, tí ó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin, òun ni kí ẹ̀yin kí ó kà sí ìríra fún yín. 24“ ‘Nípa àwọn wọ̀nyí ni ẹ le fi sọ ara yín di àìmọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 25Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 26“ ‘Àwọn ẹranko tí pátákò wọn kò là tan tàbí tí wọn kò jẹ àpọ̀jẹ jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú èyíkéyìí nínú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.