Ẹkún Jeremiah 1:19
Lamentations 1:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Mo pe àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣùgbọ́n wọ́n dà mí. Àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà mi ṣègbé sínú ìlú nígbà tí wọ́n ń wá oúnjẹ tí yóò mú wọn wà láààyè.
Lamentations 1:19 in English
Lamentations 1:19 · Berean Standard Bible
I called out to my lovers, but they have betrayed me. My priests and elders perished in the city while they searched for food to keep themselves alive.
Context
17Sioni na ọwọ́ jáde,
ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un.
Olúwa ti pàṣẹ fún Jakọbu
pé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀tá fún un
Jerusalẹmu ti di
ohun aláìmọ́ láàrín wọn. 18“Olóòtítọ́ ni Olúwa,
ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀.
Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn;
ẹ wò mí wò ìyà mi.
Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi
ni a ti kó lọ sí ìgbèkùn. 19“Mo pe àwọn ọ̀rẹ́ mi
ṣùgbọ́n wọ́n dà mí.
Àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà mi
ṣègbé sínú ìlú
nígbà tí wọ́n ń wá oúnjẹ
tí yóò mú wọn wà láààyè. 20“Olúwa, wò ó, bí mo ti wà nínú ìnira!
Tí mo sì ń jẹ̀rora nínú mi,
ìdààmú dé bá ọkàn mi
nítorí pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi gidigidi.
Ní gbangba ni idà ń parun;
ikú wà nínú ilé pẹ̀lú. 21“Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìrora mi,
ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún mi.
Àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ ìparun mi;
wọ́n yọ̀ sí ohun tí o ṣe.
Kí o mú ọjọ́ tí o ti kéde,
kí wọ́n le dàbí tèmi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.