Juda 1:4
Jude 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí àwọn ènìyàn kan ń bẹ tí wọ́n ń yọ́ wọlé, àwọn ẹni tí a ti yàn láti ìgbà àtijọ́ sí ẹ̀bi yìí, àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, tí ń yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wa padà sí wọ̀bìà, tí wọn sì ń sẹ́ Olúwa wa kan ṣoṣo náà, àní, Jesu Kristi Olúwa.
Jude 1:4 in English
Jude 1:4 · Berean Standard Bible
For certain men have crept in among you unnoticed—ungodly ones who were designated long ago for condemnation. They turn the grace of our God into a license for immorality, and they deny our only Master and Lord, Jesus Christ.
Context
2Kí àánú, àlàáfíà àti ìfẹ́ kí ó máa jẹ́ tiyín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. 3Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi tòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmí ní ìtara láti kọ̀wé sí i yín nípa ìgbàlà tí í ṣe ti gbogbo ènìyàn, n kò gbọdọ̀ má kọ̀wé sí yín, kí ń sì gbà yín ní ìyànjú láti máa jà fitafita fún ìgbàgbọ́, tí a ti fi lé àwọn ènìyàn mímọ́ lọ́wọ́ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. 4Nítorí àwọn ènìyàn kan ń bẹ tí wọ́n ń yọ́ wọlé, àwọn ẹni tí a ti yàn láti ìgbà àtijọ́ sí ẹ̀bi yìí, àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, tí ń yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wa padà sí wọ̀bìà, tí wọn sì ń sẹ́ Olúwa wa kan ṣoṣo náà, àní, Jesu Kristi Olúwa. 5Nítòótọ́, ẹ ti mọ nǹkan wọ̀nyí ní ẹ̀ẹ̀kan rí, mo fẹ́ rán an yín létí pé, lẹ́yìn tí Olúwa ti gba àwọn kan là láti ilẹ̀ Ejibiti wá, lẹ́yìn náà ni ó run àwọn tí kò gbàgbọ́. 6Àti àwọn angẹli tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìsàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá nì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.