Juda 1:17
Jude 1:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti sọ ṣáájú láti ọwọ́ àwọn aposteli Olúwa wa Jesu Kristi.
Jude 1:17 in English
Jude 1:17 · Berean Standard Bible
But you, beloved, remember what was foretold by the apostles of our Lord Jesus Christ
Context
15láti ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn, láti dá gbogbo àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run lẹ́bi ní ti gbogbo iṣẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run wọn, ti wọ́n ti fi àìwà-bí-Ọlọ́run ṣe, àti ní ti gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìwà-bí-Ọlọ́run ti sọ sí i.” 16Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní àwọn ti ń kùn, àwọn aláròyé, ti ń rìn nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn; wọn ń gbéraga nípa ara wọn, wọ́n sì ń ṣátá àwọn ènìyàn mìíràn fún èrè ara wọn. 17Ṣùgbọ́n ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti sọ ṣáájú láti ọwọ́ àwọn aposteli Olúwa wa Jesu Kristi. 18Bí wọn ti wí fún yín pé, “Nígbà ìkẹyìn àwọn ẹlẹ́gàn yóò wà, tí wọn yóò máa rìn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run ti ara wọn.” 19Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn ẹni tí ń ya ara wọn sí ọ̀tọ̀, àwọn ẹni ti ara, tí wọn kò ni Ẹ̀mí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.