Joṣua 9:12
Joshua 9:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbígbóná ní a mú oúnjẹ wa wá, nígbà tí a dì í ní ilé ní ọjọ́ tí à ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín. Ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí ó ṣe gbẹ àti bí ó sì ṣe bu nísinsin yìí.
Joshua 9:12 in English
Joshua 9:12 · Berean Standard Bible
This bread of ours was warm when we packed it at home on the day we left to come to you. But take a look, it is now dry and moldy.
Context
10àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe sí ọba àwọn Amori méjèèje tí ń bẹ ní òkè Jordani, sí Sihoni ọba Heṣboni, àti Ogu ọba Baṣani, tí wọ́n jẹ ọba ní Aṣtarotu. 11Àwọn àgbàgbà wa àti gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú wa sọ fún wa pé, ‘Ẹ mú oúnjẹ lọ́wọ́ fún ìrìnàjò yín, ẹ lọ pàdé wọn, kí ẹ sì sọ fún wọn pé, “Àwa ni ìránṣẹ́ yín, ẹ dá àdéhùn pẹ̀lú wa.” ’ 12Gbígbóná ní a mú oúnjẹ wa wá, nígbà tí a dì í ní ilé ní ọjọ́ tí à ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín. Ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí ó ṣe gbẹ àti bí ó sì ṣe bu nísinsin yìí. 13Àti ìgò wáìnì wọ̀nyí, tí àwa rọ kún tuntun ni, ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí wọ́n ti sán. Aṣọ àti bàtà wa ni ó sì ti gbó nítorí ìrìnàjò ọ̀nà jíjìn.” 14Àwọn ọkùnrin Israẹli sì yẹ oúnjẹ wọn wò, wọn kò sì wádìí ní ọwọ́ Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.