Joṣua 8:4
Joshua 8:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Pẹ̀lú àwọn àṣẹ wọ̀nyí: “Ẹ fi etí sílẹ̀ dáradára. Ẹ ba sí ẹ̀yìn ìlú náà. Ẹ má ṣe jìnnà sí i púpọ̀. Kí gbogbo yín wà ní ìmúrasílẹ̀.
Joshua 8:4 in English
Joshua 8:4 · Berean Standard Bible
with these orders: “Pay attention. You are to lie in ambush behind the city, not too far from it. All of you must be ready.
Context
2Ìwọ yóò sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, ohun ìkógun wọn àti ohun ọ̀sìn wọn ni kí ẹ̀yin mú fún ara yín. Rán ènìyàn kí wọ́n ba sí ẹ̀yìn ìlú náà.” 3Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun jáde lọ láti dojúkọ Ai. Ó sì yan ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) àwọn ọkùnrin ogun rẹ̀ ti ó yakin, ó sì rán wọn lọ ní òru. 4Pẹ̀lú àwọn àṣẹ wọ̀nyí: “Ẹ fi etí sílẹ̀ dáradára. Ẹ ba sí ẹ̀yìn ìlú náà. Ẹ má ṣe jìnnà sí i púpọ̀. Kí gbogbo yín wà ní ìmúrasílẹ̀. 5Èmi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi yóò súnmọ́ ìlú náà, nígbà tí àwọn ọkùnrin náà bá jáde sí wa, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ìṣáájú, àwa yóò sì sá kúrò níwájú u wọn. 6Wọn yóò sì lépa wa títí àwa ó fi tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà, nítorí tí wọn yóò wí pé, wọ́n ń sálọ kúrò ní ọ̀dọ̀ wa gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ṣe ní ìṣáájú. Nítorí náà bí a bá sá kúrò fún wọn,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.