Joṣua 8:27
Joshua 8:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Israẹli kó ẹran ọ̀sìn àti ìkógun ti ìlú yìí fún ara wọn, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Joṣua.
Joshua 8:27 in English
Joshua 8:27 · Berean Standard Bible
Israel took for themselves only the cattle and plunder of that city, as the LORD had commanded Joshua.
Context
25Ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ọkùnrin àti obìnrin ni ó kú ní ọjọ́ náà—gbogbo wọn jẹ́ àwọn ènìyàn Ai. 26Nítorí tí Joṣua kò fa ọwọ́ rẹ̀ tí ó di ọ̀kọ̀ mú sí ẹ̀yìn, títí ó fi pa gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú Ai run. 27Ṣùgbọ́n Israẹli kó ẹran ọ̀sìn àti ìkógun ti ìlú yìí fún ara wọn, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Joṣua. 28Joṣua sì jó Ai, ó sì sọ ọ́ di ààtàn, àní ahoro di òní yìí. 29Ó sì gbé ọba Ai kọ́ orí igi, ó sì fi kalẹ̀ síbẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. Bí oòrùn sì ti wọ̀ ni Joṣua pàṣẹ fún wọn láti sọ òkú rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní orí igi, kí wọn sì wọ́ ọ jù sí àtiwọ ẹnu ibodè ìlú náà. Wọ́n sì kó òkìtì òkúta ńlá lé e ní orí, èyí tí ó wà títí di òní yìí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.