Native Bible

Joshua 8:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Joṣua pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ sí Ai, nítorí tí èmi yóò fi ìlú náà lé ọ ní ọwọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua sì na ọ̀kọ̀ ọwọ́ rẹ̀ sí Ai.

Joshua 8:18 in English

Joshua 8:18 · Berean Standard Bible

Then the LORD said to Joshua, “Hold out your battle lance * toward Ai, for into your hand I will deliver the city.” So Joshua held out his battle lance toward Ai,

Context

16A sì pe gbogbo àwọn ọkùnrin Ai jọ láti lépa wọn, wọ́n sì lépa Joṣua títí wọ́n fi tàn wọ́n jáde nínú ìlú náà. 17Kò sì ku ọkùnrin kan ní Ai tàbí Beteli tí kò tẹ̀lé Israẹli. Wọ́n sì fi ìlẹ̀kùn ibodè ìlú náà sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n sì ń lépa àwọn ará Israẹli. 18Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Joṣua pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ sí Ai, nítorí tí èmi yóò fi ìlú náà lé ọ ní ọwọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua sì na ọ̀kọ̀ ọwọ́ rẹ̀ sí Ai. 19Bí ó ti ṣe èyí tán, àwọn ọkùnrin tí ó ba sì dìde kánkán kúrò ní ipò wọn, wọ́n sáré síwájú. Wọn wọ ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára ti iná bọ̀ ọ́. 20Àwọn ọkùnrin Ai bojú wo ẹ̀yìn, wọ́n rí èéfín ìlú náà ń gòkè lọ sí ọ̀run, ṣùgbọ́n wọn kò rí, ààyè láti sá àsálà lọ sí ibìkan kan, nítorí tí àwọn ará Israẹli tí wọ́n tí ń sálọ sí aginjù ti yípadà sí àwọn tí ń lépa wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.