Native Bible

Joshua 8:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Joṣua àti gbogbo àwọn Israẹli sì ṣe bí ẹni tí a lé padà níwájú wọn, wọ́n sì sá gba ọ̀nà aginjù.

Joshua 8:15 in English

Joshua 8:15 · Berean Standard Bible

Joshua and all Israel let themselves be beaten back before them, and they fled toward the wilderness.

Context

13Wọ́n sì yan àwọn ọmọ-ogun sí ipò wọn, gbogbo àwọn tí ó wà ní ibùdó lọ sí àríwá ìlú náà àti àwọn tí ó sá pamọ́ sí ìwọ̀-oòrùn rẹ̀. Ní òru ọjọ́ náà Joṣua lọ sí àfonífojì. 14Nígbà tí ọba Ai rí èyí, òun àti gbogbo ọkùnrin ìlú náà yára jáde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù láti pàdé ogun Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aginjù. Ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé àwọn kan wà ní ibùba ní ẹ̀yìn ìlú náà. 15Joṣua àti gbogbo àwọn Israẹli sì ṣe bí ẹni tí a lé padà níwájú wọn, wọ́n sì sá gba ọ̀nà aginjù. 16A sì pe gbogbo àwọn ọkùnrin Ai jọ láti lépa wọn, wọ́n sì lépa Joṣua títí wọ́n fi tàn wọ́n jáde nínú ìlú náà. 17Kò sì ku ọkùnrin kan ní Ai tàbí Beteli tí kò tẹ̀lé Israẹli. Wọ́n sì fi ìlẹ̀kùn ibodè ìlú náà sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n sì ń lépa àwọn ará Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.