Joṣua 8:11
Joshua 8:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì súnmọ́ tòsí ìlú náà, wọ́n sì dé iwájú u rẹ̀. Wọ́n sì pàgọ́ ní ìhà àríwá Ai. Àfonífojì sì wà ní agbede-méjì wọn àti ìlú náà.
Joshua 8:11 in English
Joshua 8:11 · Berean Standard Bible
Then all the troops who were with him marched up and approached the city. They arrived in front of Ai and camped to the north of it, with the valley between them and the city.
Context
9Nígbà náà ni Joṣua rán wọn lọ. Wọ́n sì lọ sí ibùba, wọ́n sì sùn ní àárín Beteli àti Ai, ní ìwọ̀-oòrùn Ai. Ṣùgbọ́n Joṣua wá dúró pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní òru ọjọ́ náà. 10Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Joṣua kó àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, òun àti àwọn olórí Israẹli, wọ́n wọ́de ogun lọ sí Ai. 11Gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì súnmọ́ tòsí ìlú náà, wọ́n sì dé iwájú u rẹ̀. Wọ́n sì pàgọ́ ní ìhà àríwá Ai. Àfonífojì sì wà ní agbede-méjì wọn àti ìlú náà. 12Joṣua sì ti fi bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọmọ-ogun pamọ́ sí àárín Beteli àti Ai, sí ìwọ̀-oòrùn ìlú náà. 13Wọ́n sì yan àwọn ọmọ-ogun sí ipò wọn, gbogbo àwọn tí ó wà ní ibùdó lọ sí àríwá ìlú náà àti àwọn tí ó sá pamọ́ sí ìwọ̀-oòrùn rẹ̀. Ní òru ọjọ́ náà Joṣua lọ sí àfonífojì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.