Native Bible

Joshua 7:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàsọ́tọ̀ náà, a ó fi iná pa á run, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní. Ó ti ba májẹ̀mú Olúwa jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Israẹli!’ ”

Joshua 7:15 in English

Joshua 7:15 · Berean Standard Bible

The one who is caught with the things devoted to destruction must be burned, along with all that belongs to him, because he has transgressed the covenant of the LORD and committed an outrage in Israel.’”

Context

13“Lọ, ya àwọn ènìyàn náà sí mímọ́. Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí báyìí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí, ohun ìyàsọ́tọ̀ kan ń bẹ ní àárín yín, Israẹli. Ẹ̀yin kì yóò lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá a yín títí ẹ̀yin yóò fi mú kúrò. 14“ ‘Ní òwúrọ̀, kí ẹ mú ará yín wá síwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀yà tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní agbo ilé kọ̀ọ̀kan, agbo ilé tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, ìdílé tí Olúwa bá sì mú yóò wá sí iwájú ní ẹni kọ̀ọ̀kan. 15Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàsọ́tọ̀ náà, a ó fi iná pa á run, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní. Ó ti ba májẹ̀mú Olúwa jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Israẹli!’ ” 16Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Joṣua mú Israẹli wá síwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, a sì mú ẹ̀yà Juda. 17Àwọn agbo ilé e Juda wá sí iwájú, ó sì mú agbo ilé Sera. Ó sì mú agbo ilé Sera wá síwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, a sì mú ìdílé Sabdi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.