Joṣua 6:5
Joshua 6:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ẹ bá gbọ́ ohùn fèrè náà, kí àwọn ènìyàn hó yèè ní igbe ńlá, nígbà náà ni odi ìlú náà yóò sì wó lulẹ̀, àwọn ènìyàn yóò sì lọ sí òkè, olúkúlùkù yóò sì wọ inú rẹ̀ lọ tààrà.”
Joshua 6:5 in English
Joshua 6:5 · Berean Standard Bible
And when there is a long blast of the ram’s horn and you hear its sound, have all the people give a mighty shout. Then the wall of the city will collapse * and all your people will charge straight into the city.*”
Context
3Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan pẹ̀lú gbogbo àwọn jagunjagun. Ẹ ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà. 4Jẹ́ kí àwọn àlùfáà méje gbé fèrè ìwo àgbò ní iwájú àpótí ẹ̀rí. Ní ọjọ́ keje, ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, pẹ̀lú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè. 5Nígbà tí ẹ bá gbọ́ ohùn fèrè náà, kí àwọn ènìyàn hó yèè ní igbe ńlá, nígbà náà ni odi ìlú náà yóò sì wó lulẹ̀, àwọn ènìyàn yóò sì lọ sí òkè, olúkúlùkù yóò sì wọ inú rẹ̀ lọ tààrà.” 6Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ọmọ Nuni pe àwọn àlùfáà ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa náà kí àwọn àlùfáà méje tí ó ru fèrè ìwo wà ní iwájú u rẹ̀.” 7Ó sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ lọ, kí ẹ sì yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ tí ó hámọ́ra kọjá ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.