Joṣua 6:25
Joshua 6:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Joṣua dá Rahabu panṣágà pẹ̀lú gbogbo ìdílé e rẹ̀ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tirẹ̀ sí nítorí pé, ó pa àwọn ọkùnrin tí Joṣua rán gẹ́gẹ́ bí ayọ́lẹ̀wò sí Jeriko mọ́. Ó sì ń gbé láàrín ará Israẹli títí di òní yìí.
Joshua 6:25 in English
Joshua 6:25 · Berean Standard Bible
And Joshua spared Rahab the prostitute, with her father’s household and all who belonged to her, because she hid the men Joshua had sent to spy out Jericho. So she has lived among the Israelites to this day.
Context
23Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó lọ ṣe ayọ́lẹ̀wò wọlé lọ, wọ́n sì mú Rahabu jáde, baba rẹ̀, ìyá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. Wọ́n sì mú gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde, wọ́n sì fi wọ́n sí ibìkan ní ìta ibùdó àwọn ará Israẹli. 24Nígbà náà ni wọ́n sun gbogbo ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà nínú u rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fi fàdákà, wúrà ohun èlò idẹ àti irin sínú ìṣúra ilé Olúwa. 25Ṣùgbọ́n Joṣua dá Rahabu panṣágà pẹ̀lú gbogbo ìdílé e rẹ̀ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tirẹ̀ sí nítorí pé, ó pa àwọn ọkùnrin tí Joṣua rán gẹ́gẹ́ bí ayọ́lẹ̀wò sí Jeriko mọ́. Ó sì ń gbé láàrín ará Israẹli títí di òní yìí. 26Ní àkókò náà Joṣua sì búra pé, “Ègún ni fún ẹni náà níwájú Olúwa tí yóò dìde, tí yóò sì tún ìlú Jeriko kọ́:
“Pẹ̀lú ikú àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni
yóò fi pilẹ̀ rẹ̀;
ikú àbíkẹ́yìn rẹ̀ ní yóò fi
gbé ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ ró.” 27Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wà pẹ̀lú Joṣua; òkìkí rẹ̀ sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.