Joṣua 5:6
Joshua 5:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ará Israẹli rìn ní aginjù fún ogójì ọdún títí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó tó ogun n jà nígbà tí wọ́n kúrò ni Ejibiti fi kú, nítorí wọn kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa. Nítorí Olúwa ti búra fún wọn pé wọn kò ní rí ilẹ̀ tí òun ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn láti fi fun wa, ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin.
Joshua 5:6 in English
Joshua 5:6 · Berean Standard Bible
For the Israelites had wandered in the wilderness forty years, until all the nation’s men of war who had come out of Egypt had died, since they did not obey the LORD. So the LORD vowed never to let them see the land He had sworn to their fathers to give us, a land flowing with milk and honey.
Context
4Wàyí o, ìdí tí Joṣua fi kọ wọ́n nílà nìyìí. Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó ti Ejibiti jáde wá, gbogbo àwọn ọkùnrin ogun kú ní aginjù ní ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti. 5Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, gbogbo àwọn ọkùnrin tó jáde láti Ejibiti ni a ti kọ ní ilà, síbẹ̀ gbogbo ènìyàn tí a bí nínú aginjù lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní Ejibiti ni wọn kò kọ ní ilà. 6Àwọn ará Israẹli rìn ní aginjù fún ogójì ọdún títí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó tó ogun n jà nígbà tí wọ́n kúrò ni Ejibiti fi kú, nítorí wọn kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa. Nítorí Olúwa ti búra fún wọn pé wọn kò ní rí ilẹ̀ tí òun ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn láti fi fun wa, ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin. 7Bẹ́ẹ̀ ni ó gbé àwọn ọmọ wọn dìde dípò wọn, àwọn wọ̀nyí sì ni Joṣua kọ ní ilà. Wọ́n wà ní aláìkọlà nítorí a kò tí ì kọ wọ́n ní ilà ní ojú ọ̀nà. 8Lẹ́yìn ìgbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà kọ ilà tan, wọ́n dúró ní ibi tí wọ́n wà ní ibùdó títí ilà wọn fi jinná.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.