Joṣua 5:12
Joshua 5:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Manna náà sì tan ní ọjọ́ kejì tí wọ́n jẹ oúnjẹ tí ilẹ̀ náà mú jáde, kò sì sí manna kankan mọ́ fún àwọn ará Israẹli, ṣùgbọ́n ní ọdún náà wọ́n jẹ ìre oko ilẹ̀ Kenaani.
Joshua 5:12 in English
Joshua 5:12 · Berean Standard Bible
And the day after they had eaten from the produce of the land, the manna ceased. There was no more manna for the Israelites, so that year they began to eat the crops of the land of Canaan.
Context
10Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù náà, nígbà tí wọ́n pàgọ́ ní Gilgali ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko, àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ọdún àjọ ìrékọjá. 11Ní ọjọ́ kejì àjọ ìrékọjá, ní ọjọ́ náà gan an ni, wọ́n jẹ nínú àwọn ìre oko ilẹ̀ náà: àkàrà aláìwú, àti ọkà yíyan. 12Manna náà sì tan ní ọjọ́ kejì tí wọ́n jẹ oúnjẹ tí ilẹ̀ náà mú jáde, kò sì sí manna kankan mọ́ fún àwọn ará Israẹli, ṣùgbọ́n ní ọdún náà wọ́n jẹ ìre oko ilẹ̀ Kenaani. 13Nígbà tí Joṣua súnmọ́ Jeriko, ó wo òkè ó sì rí ọkùnrin kan tí ó dúró ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú idà ní ọwọ́ rẹ̀. Joṣua sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bi í pé, “Ǹjẹ́ ìwọ wà fún wa tàbí fún ọ̀tá a wa?” 14“Kì í ṣe fún èyíkéyìí ó fèsì, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí ogun Olúwa ni mo wá nísinsin yìí.” Nígbà náà ni Joṣua sì wólẹ̀ ní iwájú u rẹ̀ ní ìbẹ̀rù, ó sì bi í léèrè, “Kí ni Olúwa ní í sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.